Jeremiah 10:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́, ni kí o bínú sí kí ó pọ̀, ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ; nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tu ibinu rẹ si ori awọn orilẹ-ède, ti kò mọ̀ ọ, ati sori awọn idile ti kò ke pè orukọ rẹ, nitoriti nwọn ti jẹ Jakobu run, nwọn si gbe e mì, nwọn si pa a run tan, nwọn si sọ ibugbe rẹ̀ di ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tú ìbínú rẹ síta sórí àwọn orílẹ̀ èdè tí kò mọ̀ ọ́, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jákọ́bù run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátapáta, wọ́n sì ti ba ilẹ̀ ibùgbé rẹ̀ jẹ́.