Jeremiah 10:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí, wọn kò lè sọ̀rọ̀, gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọn nítorí pé wọn kò lè dá rìn. Ẹ má bẹ̀rù wọn nítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn nàro bi igi ọpẹ, ṣugbọn nwọn kò fọhùn: gbigbe li a ngbe wọn, nitori nwọn kò le rin. Má bẹ̀ru wọn; nitori nwọn kò le ṣe buburu, bẹ̃li ati ṣe rere, kò si ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n nàró bí igi ọ̀pẹ, òrìṣà wọn kò le è ṣọ̀rọ̀. Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé wọn nítorí pé wọn kò lè rìn. Má ṣe bẹ̀rù wọn; wọn kò le è ṣe ibi kankan bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”