Jeremiah 10:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi, ati wúrà láti ìlú Ufasi. Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n, ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà. Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupa ati ti elése àlùkò, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fadaka ti a fi ṣe awo ni a mu lati Tarṣiṣi wá, ati wura lati Upasi wá, iṣẹ oniṣọna, ati lọwọ alagbẹdẹ: alaro ati elese aluko ni aṣọ wọn: iṣẹ ọlọgbọ́n ni gbogbo wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sílífà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tásísì, àti wúrà láti Lépásì; èyí tí àwọn onísọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti eléṣé àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́.