Jeremiah 11:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àwọn ìlú ti pọ̀ tó ní ilẹ̀ Juda bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa ibẹ̀ pọ̀ tó. Bákan náà, Jerusalẹmu, bí òpópó ṣe pọ̀ tó ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun turari sí Baali, tí ó jẹ́ ohun ìtìjú, ṣe pọ̀ tó ninu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃ni iye ọlọrun rẹ, iwọ Juda, ati bi iye ita Jerusalemu, bẹ̃ni iye pẹpẹ ti ẹnyin ti tẹ́ fun ohun itìju nì, pẹpẹ lati sun turari fun Baali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí iye àwọn ìlú yín ṣe pọ̀ tó náà ni àwọn òrìṣà yín. Ìwọ Júdà: àwọn pẹpẹ tí o ti pèsè fún jíjó tùràrí sí àwọn Báálì, òrìṣà yẹ̀yẹ́ sì pọ̀ bí iye òpópó tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.’