Jeremiah 11:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina máṣe gbadura fun awọn enia yi, bẹ̃ni ki o má si ṣe gbe ohùn ẹkun tabi ti adura soke fun wọn, nitori emi kì yio gbọ́ ni igba ti nwọn ba kigbe pè mi, ni wakati wahala wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé Èmi kò ní dẹtí sí wọn ní ìgbà ìpọ́njú.