Jeremiah 11:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kini olufẹ mi ni iṣe ni ile mi? nigbati nwọn nṣe buburu pupọ bayi? adura on ẹran mimọ́ ha le mu ibi kọja kuro lọdọ rẹ? bi o ba ri bayi? nigbana jẹ ki inu rẹ ki o dùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kí ni àyànfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹ́ḿpìlì mi, bí ó ṣe ń hu oríṣiríṣi ìwà àrékérekè? Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀? Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀, inú rẹ̀ yóò máa dùn.”