Jeremiah 11:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o gbìn ọ, ti sọ̀rọ ibi si ọ, nitori buburu ile Israeli, ati ile Juda, ti nwọn ti ṣe si ara wọn lati ru ibinu mi soke ni sisun turari fun Baali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Ísírẹ́lì àti Júdà ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí fún Báálì.