Jeremiah 11:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ti dàbí ọ̀dọ́ àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; N kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé: “Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀; jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè, kí a mọ́ lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”