Jeremiah 11:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó ń dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun, onidajọ otitọ ti ndan aiya ati inu wò, emi o ri igbẹsan rẹ lori wọn: nitori iwọ ni mo fi ọ̀ran mi le lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ OLÚWA àwọn ọmọ ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn; nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.