Jeremiah 11:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní òun óo jẹ wọ́n níyà; àwọn ọdọmọkunrin wọn yóo kú lójú ogun, ìyàn ni yóo sì pa àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, wò o, emi o bẹ̀ wọn wo, awọn ọdọmọkunrin o ti ọwọ idà kú, ọmọ wọn ọkunrin ati ọmọ wọn obinrin yio kú nipa iyàn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.