Jeremiah 11:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, li ọjọ ti mo mu wọn ti ilẹ Egipti jade, lati inu ileru irin wipe, Gbà ohùn mi gbọ́, ki ẹ si ṣe gẹgẹ bi emi ti paṣẹ fun nyin: bẹ̃ni ẹnyin o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn májẹ̀mú tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Éjíbítì, láti ìléru ìyọ́rin wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín