Jeremiah 11:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óo mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé n óo fún wọn ní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin,’ bí ó ti rí ní òní.” Mo bá dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki emi ki o le mu ileri mi ṣẹ, ti mo ti bura fun awọn baba nyin, lati fun wọn ni ilẹ ti nṣàn fun wara ati fun oyin, gẹgẹ bi o ti ri li oni: mo si dahùn mo si wipe, Amin, Oluwa!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.” Mo sì dáhùn wí pé, “Àmí, OLÚWA.”