Jeremiah 11:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA tún sọ fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda ati ní àwọn òpópó Jerusalẹmu, pé kí wọn fetí sí ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí wọ́n sì ṣe bí ó ti wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun mi pe, Kede gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi ki ẹ si ṣe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìlérí yìí, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn.