Jeremiah 11:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, títí tí ó sì fi di òní, n kò yé kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn èmi OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ni kikilọ mo kilọ fun awọn baba nyin lati ọjọ ti mo ti mu wọn wá lati ilẹ Egipti, titi di oni, emi si nyara kilọ fun wọn, mo si nsọ wipe, Ẹ gbà ohùn mi gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.”