Jeremiah 11:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sibẹsibẹ wọn kò gbọ́; wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, olukuluku ń ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ majẹmu yìí ṣẹ mọ́ wọn lára, bí mo ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọn ṣe, ṣugbọn tí wọn kò ṣe.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹsibẹ nwọn kò gbọ́, nwọn kò tẹti silẹ, nwọn si rìn, olukuluku wọn ni agidi ọkàn buburu wọn: nitorina emi o mu gbogbo ọ̀rọ majẹmu yi wá sori wọn, ti mo paṣẹ fun wọn lati ṣe; nwọn kò si ṣe e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ bi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé.’ ”