Jeremiah 12:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédéé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìsòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?