Jeremiah 12:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè. Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan. Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè, nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti gbin alikama, ṣugbọn nwọn o ka ẹ́gun, nwọn ti fi irora ẹ̀dun mu ara wọn, ṣugbọn nwọn kì yio ri anfani: ki oju ki o tì nyin nitori ère nyin, nitori ibinu gbigbona Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn. Kí ojú kí ó tìyín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná OLÚWA.