Jeremiah 12:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi si gbogbo awọn aladugbo buburu mi ti nwọn fi ọwọ kan ogún mi ti mo ti mu enia mi, Israeli, jogun. Sa wò o, emi o fa wọn tu kuro ni ilẹ wọn, emi o si fà ile Juda tu kuro larin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Júdà tu kúrò ní àárin wọn.