Jeremiah 12:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀, tí koríko oko yóo rọ? Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé, nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio ti pẹ to ti ilẹ yio fi ma ṣọ̀fọ, ati ti ewe igbẹ gbogbo yio rẹ̀ nitori ìwa-buburu awọn ti mbẹ ninu rẹ̀? ẹranko ati ẹiyẹ nṣòfò nitori ti nwọn wipe, on kì o ri ẹ̀hin wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà, tí gbogbo ewéko ìgbẹ́ sì ń rọ? Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀. Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé, “Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ síwa.”