Jeremiah 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́, báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré? Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba ba ẹlẹsẹ rìn, ti ãrẹ si mu ọ, iwọ o ha ti ṣe ba ẹlẹṣin dije? ati pẹlu ni ilẹ alafia, bi iwọ ba ni igbẹkẹle, kini iwọ o ṣe ninu ẹkún odò Jordani?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́sẹ̀ díje, tí àárẹ̀ sì mú ọ, báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje? Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà, báwo ni ìwọ ó ṣe ṣe nínú ihà Jọ́dánì?