Jeremiah 12:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàá ati àwọn ará ilé baba rẹ ti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ; àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ: Má gbẹ́kẹ̀lé wọn, bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori pẹlupẹlu, awọn arakunrin rẹ, ati ile baba rẹ, awọn na ti hùwa ẹ̀tan si ọ, lõtọ, awọn na ti ho le ọ: Má gbẹkẹle wọn, bi nwọn tilẹ ba ọ sọ̀rọ daradara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé— ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ Wọ́n ti hó lé ọ lórí; Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáadáa.