Jeremiah 12:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni? Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni? Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ, ẹ kó wọn wá jẹun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ogún mi di ẹranko ọ̀wawa fun mi, ẹranko yi i kakiri, ẹ lọ, ẹ ko gbogbo ẹran igbẹ jọ pọ̀, ẹ mu wọn wá jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìní kò ha ti dàbí ẹyẹ kanna-kánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì kọ tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i? Lọ kí o lọ ṣe àkójọ gbogbo àwọn ẹranko búburú, kó wọn wá láti wá parun.