Jeremiah 13:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia buburu yi, ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi, ti nrin ni agidi ọkàn wọn, ti o si nrin tọ̀ awọn ọlọrun miran, lati sìn wọn ati lati foribalẹ fun wọn, yio si dabi àmure yi, ti kò yẹ fun ohunkohun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun.