Jeremiah 13:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi amure iti lẹ̀ mọ ẹgbẹ enia, bẹ̃ni mo ṣe ki gbogbo ile Israeli ati gbogbo ile Juda ki o lẹ̀ mọ mi lara, li Oluwa wi, ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ati orukọ ati ogo, ati iyìn, ṣugbọn nwọn kò fẹ igbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà mọ́ mi,’ ni OLÚWA wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’