Jeremiah 13:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ki iwọ ki o sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún: nwọn o si wi fun ọ pe, A kò ha mọ̀ nitõtọ pe, gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún wọn, ‘Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí: Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’