Jeremiah 13:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo máa sọ wọ́n lu ara wọn. Baba ati ọmọ yóo máa kọlu ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní ṣàánú wọn, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yọ́nú sí wọn débi pé kí n má fẹ́ pa wọ́n run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o tì ekini lu ekeji, ani awọn baba ati awọn ọmọkunrin pọ̀, li Oluwa wi: emi kì yio dariji, bẹ̃ni emi kì o ṣãnu, emi kì yio ṣe iyọ́nu, lati má pa wọn run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni OLÚWA wí: Èmi kì yóò dáríjìn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti má a pa wọ́n run.’ ”