Jeremiah 13:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́, tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí? Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kini iwọ o wi, nigbati on o fi awọn ti iwọ ti kọ́ lati ṣe korikosun rẹ jẹ olori lori rẹ, irora kì yio ha mu ọ bi obinrin ti nrọbi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí OLÚWA bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?