Jeremiah 13:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín, gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin, ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé! Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti ri panṣaga rẹ, ati yiyan rẹ bi ẹṣin, buburu ìwa-agbere rẹ, ati ìwa irira rẹ lori oke ati ninu oko. Egbe ni fun ọ, iwọ Jerusalemu! iwọ kò le di mimọ́, yio ha ti pẹ to!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àìlójútì aṣẹ́wó rẹ! Mo ti rí ìwà ìkórìíra rẹ lórí òkè àti ní pápá. Ègbé ni fún ọ ìwọ Jérúsálẹ́mù! Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”