Jeremiah 13:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si lọ si odò Ferate, mo si walẹ̀, mo si mu àmure na jade kuro ni ibi ti emi ti fi i pamọ si, sa wò o, àmure na di hihù, kò si yẹ fun ohunkohun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo lọ sí Pérátì mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsín yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.