Jeremiah 14:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé, “Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri, wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn; nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA, nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn, yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà OLÚWA kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”