Jeremiah 14:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ li orukọ mi, ti emi kò rán; sibẹ nwọn wipe, Idà ati ìyan kì yio wá sori ilẹ yi; nipa idà, pẹlu ìyan, ni awọn woli wọnyi yio ṣegbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èyí ni OLÚWA sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.