Jeremiah 14:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé, ‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru, kí ó má dáwọ́ dúró, nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe: oju mi sun omije li oru ati li ọsan, kì yio si dá, nitoriti a ti ṣa wundia ọmọbinrin enia mi li ọgbẹ nla kikoro gidigidi ni lilù na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn báyìí pé: “ ‘Jẹ́ kí omijé dà lójú mi lọ́sàn-án àti lóru láìdúró. Fún wúndíá mi-àwọn ènìyàn mi tí a dá lọ́gbẹ́ àti lílù bolẹ̀.