Jeremiah 14:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko, àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀! Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú, àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀. Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà, wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi emi ba jade lọ si papa, sa wò o, a ri awọn ti a fi idà pa! bi emi ba si wọ inu ilu lọ, sa wò o, awọn ti npa ọ̀kakà ikú nitori iyan! nitori awọn, ati awọn woli, ati awọn alufa nwọ́ lọ si ilẹ ti nwọn kò mọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”