Jeremiah 14:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn, ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀? Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò? OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni? Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o le mu ojo rọ̀ ha wà lọdọ awọn oriṣa awọn keferi? tabi ọrun le rọ̀ òjo? iwọ ha kọ́, Oluwa Ọlọrun wa? awa si nreti rẹ: nitori iwọ li o da gbogbo nkan wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀ èdè le ṣe kí òjò rọ̀? Ǹjẹ́ àwọ̀sánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí? Rárá, ìwọ ni, OLÚWA Ọlọ́run wa. Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.