Jeremiah 14:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi, àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi. Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo, ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn, wọ́n káwọ́ lérí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọlọla wọn si ti rán awọn ọmọ wẹrẹ lọ si odò: nwọn wá si kanga, nwọn kò ri omi; nwọn pada pẹlu agbè wọn lofo, oju tì wọn, idãmu mu wọn, nwọn si bo ori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi. Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo; ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn.