Jeremiah 15:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, bayi li Oluwa wi, Bi iwọ ba yipada, nigbana li emi o si tun mu ọ pada wá, iwọ o si duro niwaju mi: bi iwọ ba si yà eyi ti iṣe iyebiye kuro ninu buburu, iwọ o dabi ẹnu mi: nwọn o si yipada si ọ; ṣugbọn iwọ máṣe yipada si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà báyìí ni OLÚWA wí: “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di ọ̀gbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn