Jeremiah 15:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si ṣe ọ fun awọn enia yi bi odi idẹ ati alagbara: nwọn o si ba ọ jà, ṣugbọn nwọn kì yio le bori rẹ, nitori emi wà pẹlu rẹ, lati gbà ọ là ati lati gbà ọ silẹ, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni OLÚWA wí.