Jeremiah 15:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín, tí mo sì pa yín run. Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni OLÚWA wí “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́ lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run; Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.