Jeremiah 15:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà, ní ẹnubodè ilẹ̀ náà. Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn; mo ti pa àwọn eniyan mi run, nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ Èmi yóò fi atẹ fẹ́ wọn sí ẹnu ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìsọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tíì yí padà kúrò lọ́nà wọn.