Jeremiah 15:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ó bí ọmọ meje ṣe àárẹ̀, ó sì dákú, oòrùn rẹ̀ wọ̀ lọ́sàn-án gangan. Ìtìjú ati àbùkù bá a. N óo jẹ́ kí ọ̀tá fi idà pa àwọn tí wọ́n kù ninu wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o bi meje nṣọ̀fọ o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ; õrùn rẹ̀ wọ̀ l'ọsan, oju ntì i, o si ndamu: iyoku ninu wọn l'emi o si fifun idà niwaju awọn ọta wọn, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn-án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè wá síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni OLÚWA wí.