Jeremiah 16:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí o bá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn eniyan náà tán, bí wọn bá bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú yìí nípa wa? Kí ni a ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni a ṣẹ OLUWA Ọlọrun wa?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nigbati iwọ o ba fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi han enia yi, nwọn o wi fun ọ pe, Ẽṣe ti Oluwa fi sọ̀rọ gbogbo ohun buburu nla yi si wa, tabi kini aiṣedede wa? tabi ẹ̀ṣẹ kini awa da si Oluwa Ọlọrun wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘È é ṣe tí OLÚWA ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kínni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa sẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run wa?’