Jeremiah 16:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni iwọ o wi fun wọn pe, Nitoripe awọn baba nyin ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, ti nwọn si rìn tọ̀ ọlọrun miran lọ, ti nwọn si sìn wọn, ti nwọn si foribalẹ fun wọn, ti nwọn kọ̀ mi silẹ, ti nwọn kò pa ofin mi mọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni OLÚWA wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́.