Jeremiah 16:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́. Ẹ̀yin gan-an ti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn baba yín lọ, ẹ wò bí olukuluku yín tí ń tẹ̀lé agídí ọkàn rẹ̀, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu pe, ẹnyin ti ṣe buburu jù awọn baba nyin lọ: nitorina sa wò o, ẹnyin rìn olukuluku nyin, ni agidi ọkàn buburu rẹ̀, ki ẹnyin ki o má ba gbọ́ temi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Ní bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ṣe ń tẹ̀lé ọkàn líle rẹ̀, dípò èyí tí ó yẹ kí ẹ fi gbọ́ tèmi.