Jeremiah 16:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra mọ́ pé, ‘Bí OLUWA, tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tí ń bẹ,’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, sa wò o, Bayi li Oluwa wi, ọjọ mbọ̀, ti a kì o wi mọ́ pe, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni OLÚWA wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú OLÚWA wà láàyè OLÚWA ń bẹ Ẹni tí ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì.’