Jeremiah 16:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn wọn yóo máa búra pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ, ẹni tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde láti ilẹ̀ àríwá ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó lé wọn lọ.’ N óo mú wọn pada sórí ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade wá kuro ni ilẹ ariwa, ati kuro ni ilẹ nibiti o ti lé wọn si: emi o si tun mu wọn wá si ilẹ wọn, eyiti mo fi fun awọn baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí OLÚWA ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn