Jeremiah 16:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo gbẹ̀san àìdára wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní ìlọ́po meji, nítorí wọ́n ti fi ohun ìríra wọn sọ ilẹ̀ mi di eléèérí. Wọ́n sì ti kó oriṣa ìríra wọn kún ilẹ̀ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́poméjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì ti kún ohun ìní mi pẹ̀lú ẹ̀gbin òrìṣà wọn.”