Jeremiah 16:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi, ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ, láti gbogbo òpin ayé, wọn yóo máa wí pé: “Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún, ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, alágbára àti okun mi ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú Áà! àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá láti òpin ayé wí pé, “Àwọn baba ńlá wa kò ní ohunkan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìsà, ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.