Jeremiah 16:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o kú ikú àrun; a kì yio ṣọ̀fọ wọn; bẹ̃ni a kì yio si sin wọn; nwọn o si di àtan lori ilẹ: a o fi idà ati ìyan run wọn, ati okú wọn yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wọn yóò kú ikú àrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”