Jeremiah 16:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Má wọ ilé tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, má lọ máa kọrin arò, tabi kí o bá wọn kẹ́dùn, nítorí mo ti mú alaafia mi ati ìfẹ́ mi ati àánú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi, máṣe wọ inu ile ãwẹ̀, bẹ̃ni ki iwọ máṣe lọ sọ̀fọ, tabi lọ pohùnrere ẹkun wọn; nitori emi ti mu alafia mi kuro lọdọ enia yi, li Oluwa wi, ani ãnu ati iyọ́nu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí báyìí ni OLÚWA wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má se lọ ibẹ̀ láti káànú tàbí sọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú ìbùkún, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni OLÚWA wí.