Jeremiah 17:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA, ìwọ ni Israẹli gbójú lé, ojú yóo ti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. A óo kọ orúkọ àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ sórí ilẹ̀, yóo sì parẹ́, nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA, orísun omi ìyè, sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ni ireti Israeli! gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ yio dãmu, awọn ti o yẹ̀ kuro lọdọ mi, ni a o kọ orukọ wọn sinu ẽkuru, si ori ilẹ, nitori nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, orisun omi ìye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA olùgbẹ́kẹ̀lé Ísírẹ́lì gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì: gbogbo àwọn tí ó padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ọ́ kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ OLÚWA orísun omi ìyè wọn sílẹ̀.